1 Sámúẹ́lì 22 BMY

Dáfídì Sálọ Sí Ihò Ádúlámù.

1 Dáfídì sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Ádúlámù; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀.

2 Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ipọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbésè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó iwọ̀n irinwó ọmọkùnrin.

3 Dáfídì sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mísípa tí Móábù: ó sì wí fún ọba Móábù pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.”

4 Ó sì mú wọn wá ṣíwájú ọba Móábù; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dáfídì fí wà nínú ihò náà.

5 Gádì wòlíì sí wí fún Dáfídì pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Júdà.” Nígbà náà ni Dáfídì sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hárétì.

Ṣọ́ọ̀lù Pa Àwọn Àlùfáà Nóbù

6 Ṣọ́ọ̀lù si gbọ́ pé a rí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ ní Gíbéà lábẹ́ igi kan ní Rámà; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í.

7 Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ara Bẹ́ńjámínì, ọmọ Jésè yóò há fún olúkùlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí?

8 Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jésè mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

9 Dóégì ara Édómù tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jésè, ó wá sí Nóbù, sọ́dọ̀ Áhímélékì ọmọ Áhítúbì.

10 Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ́, kò sí fún un ni idà Gòláyátì ara Fílístínì.”

11 Ọba sì ránṣẹ́ pe Áhímélékì àlùfáà, ọmọ Áhítúbì àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nóbù: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba.

12 Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Áhítúbì.”Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí Olúwa mi.”

13 Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi dìmọ̀lù sí mi, ìwọ àti ọmọ Jésè, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèré fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

14 Áhímélékì sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni Olúwa rẹ̀ tí ó jẹ́ olóótọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dáfídì, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ni ilé rẹ.

15 Òní l'èmi ó ṣẹṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tabi púpọ̀.”

16 Ọba sì wí pé, “Áhímélékì, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.”

17 Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dáfídì, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi,”Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n.

18 Ọba sì wí fún Dóégì pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pá àwọn àlùfáà!” Dóégì ará Édómù sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin (85) ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ Éfọ́dú.

19 Ó sì fi ojú idà pa ara Nóbù, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn.

Ábíátarì Sá Àsálà Tọ Dáfídì.

20 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Áhímélékì ọmọ Áhítúbì tí a ń pè ní Ábíátarì sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ Dáfídì lọ.

21 Ábíátarì sì fi han Dáfídì pé Ṣọ́ọ̀lù pá àwọn àlùfáà Olúwa tán.

22 Dáfídì sì wí fún Ábíátarì pé, “Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Dóégì ará Édómù ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún Ṣọ́ọ̀lù: nítorí mi ni a ṣe pá gbogbo ìdílé baba rẹ.

23 Ìwọ jókòó níhin lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mi mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ: Ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31