11 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kíṣì yìí. Ṣé Ṣọ́ọ̀lù wà lára àwọn wòlíì ní?”
12 Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, “Ta ni baba wọn?” Ó ti di ohun tí a fi ń dáṣà pé, ǹjẹ́ Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì bí?
13 Lẹ́yìn tí Ṣọ́ọ̀lù dákẹ́ sísọ àṣọtẹ́lẹ̀, ó lọ sí ibi gíga.
14 Nísinsìn yìí, arákùnrin baba Ṣọ́ọ̀lù béèrè lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni ẹ lọ?”Ó wí pé, “À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Sámúẹ́lì.
15 Arákùnrin baba Ṣọ́ọ̀lù wí pé, “Sọ fún mi ohun tí Sámúẹ́lì wí fún un yín.”
16 Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Sámúẹ́lì sọ nípa ọba jíjẹ.
17 Sámúẹ́lì pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí iwájú Olúwa ní Mísípà.