17 Sámúẹ́lì pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí iwájú Olúwa ní Mísípà.
18 Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Èmi mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Éjíbítì àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’
19 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”
20 Nígbà Sámúẹ́lì mú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.
21 Ó kó ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣíwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Mátírì. Ní ìparí a sì yan Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i,
22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrin àwọn ẹrù.”
23 Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàárin àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè.