1 Sámúẹ́lì 13:6-12 BMY

6 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàárin àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kàǹga gbígbẹ.

7 Àwọn Hébérù mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jọ́dánì sí ilẹ̀ Gádì àti Gílíádì.Ṣọ́ọ̀lù wà ní Gílígálì ṣíbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù.

8 Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Sámúẹ́lì dá; ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì kò wá sí Gílígálì, àwọn ènìyàn Ṣọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká.

9 Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi,” Ṣọ́ọ̀lù sì rú ẹbọ sísun náà.

10 Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ náà, Sámúẹ́lì sì dé, Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti lọ kí i.

11 Sámúẹ́lì sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.”Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Fílístínì sì kó ara wọ́n jọ ní Míkímásì,

12 mo rò pé, ‘Àwọn Fílístínì yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gílígálì nísinsìn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipa láti rú ẹbọ sísun náà.”