1 Sámúẹ́lì 15:1-7 BMY

1 Sámúẹ́lì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi ni Olúwa rán láti fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì; fetí sílẹ̀ láti gbọ́ Iṣẹ́ tí Olúwa rán mi sí ọ́.

2 Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára wí: Èmi yóò jẹ àwọn Ámálékì níyà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Ísírẹ́lì nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Éjíbítì.

3 Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọlu Ámálékì, kí o sì pa gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ ti wọn ní àparun. Má ṣe dá wọn sí, pa ọkùnrin àti obìnrin wọn, ọmọ kékeré àti ọmọ ọmú, màlúù àti àgùntàn, ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.”

4 Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù kó àwọn ènìyàn jọ, ó sì ka iye wọn ní Táláémù, wọ́n sì jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (200,000) àwọn ológun ẹlẹ́ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹgbàárún àwọn ọkùnrin Júdà (10,000).

5 Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí ìlú Ámálékì ó sì gọ dè wọ́n ní àfonífojì kan.

6 Nígbà náà ni ó wí fún àwọn Kénáítì pé, “Ẹ lọ, kúrò ní Ámálékì kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn; nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè ti Éjíbítì wá.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kénáítì lọ kúrò láàrin àwọn Ámálékì.

7 Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù kọlu àwọn Ámálékì láti Háfílà dé Súrì, tí ó fi dé ìlà oòrùn Éjíbítì.