1 Sámúẹ́lì 15:9-15 BMY

9 Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátapáta ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì ní láárí ni wọ́n parun pátapáta.

10 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sámúẹ́lì wá pé:

11 “Èmi káànú gidigidi pé mo fi Ṣọ́ọ̀lù jọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Sámúẹ́lì sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì képe Olúwa ní gbogbo òru náà.

12 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Sámúẹ́lì sì dìde láti lọ pàdé Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Ṣọ́ọ̀lù ti wá sí Kámẹ́lì. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gílígálì.”

13 Nígbà tí Sámúẹ́lì sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, “Olúwa bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí Olúwa pa láṣẹ.”

14 Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Èwo wá ni igbe àgùntàn tí mo ń gbọ́ ní etí mi? Kí ni igbe màlúù ti mo ń gbọ́ yìí?”

15 Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ogun ní o mú wọn láti Ámálékì wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tó kù run pátapáta.”