1 Sámúẹ́lì 16:1-7 BMY

1 Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa dárò Ṣọ́ọ̀lù, nígbà tí ó jẹ́ pé mo ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì? Rọ òróró kún inú ìwo rẹ, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, Èmi rán ọ sí Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Èmi ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ ọba.”

2 Sùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé; “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ? Bí Ṣọ́ọ̀lù bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi.” Olúwa wí pé, “Mú abo ẹgbọ̀rọ̀ màlúù kan pẹ̀lú rẹ, kí o sì wí pé, ‘Èmi wá láti wá rúbọ sí Olúwa.’

3 Pe Jésè wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́. Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fi hàn ọ́.”

4 Sámúẹ́lì ṣe ohun tí Olúwa sọ. Nígbà tí ó dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àyà gbogbo àgbààgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?”

5 Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rúbọ sí Olúwa. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rúbọ pẹ̀lú ù mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jésè sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.

6 Nígbà tí wọ́n dé, Sámúẹ́lì rí Élíábù, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa.

7 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”