11 Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dáfídì pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dáfídì yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.
12 Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ̀rù Dáfídì nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì, ṣùgbọ́n ó ti fi Ṣọ́ọ̀lù sílẹ̀.
13 Ó sì lé Dáfídì jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dáfídì ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun.
14 Nínú ohun tí ó bá ṣe, ó ń ní àṣeyọrí ńlá, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
15 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ni wọ́n fẹ́ràn Dáfídì, nítorí ó darí wọn ní ìgbòkègbodò ogun wọn.
17 Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Mérábù. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Ṣọ́ọ̀lù wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè síi. Jẹ́ kí àwọn Fílístínì ṣe èyí.”