13 Ó sì lé Dáfídì jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dáfídì ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun.
14 Nínú ohun tí ó bá ṣe, ó ń ní àṣeyọrí ńlá, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
15 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ni wọ́n fẹ́ràn Dáfídì, nítorí ó darí wọn ní ìgbòkègbodò ogun wọn.
17 Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Mérábù. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Ṣọ́ọ̀lù wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè síi. Jẹ́ kí àwọn Fílístínì ṣe èyí.”
18 Ṣùgbọ́n Dáfídì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Ísírẹ́lì, tí èmi yóò di àna ọba?”
19 Nígbà tí àkókò tó fún Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, láti fi fún Dáfídì, ni a sì fi fún Ádíríélì ara Méhólátì ní aya.