2 Láti ọjọ́ náà Ṣọ́ọ̀lù pa Dáfídì mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́.
3 Jónátanì bá Dáfídì dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.
4 Jónátanì sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dáfídì pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀.
5 Ohunkóhun tí Ṣọ́ọ̀lù bá rán an láti ṣe, Dáfídì máa ṣe ní àṣeyọrí, Ṣọ́ọ̀lù náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrin àwọn ológun. Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Ṣọ́ọ̀lù lọ́rùn pẹ̀lú.
6 Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti pa Fílístínì, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Ísírẹ́lì wá láti pàdé ọba Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tamborínì àti ohun èlò orin.
7 Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé:“Ṣọ́ọ̀lù pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀Dáfídì sì pa ẹgbẹgbàárún ní tirẹ̀.”
8 Ṣọ́ọ̀lù sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dáfídì pẹ̀lú ẹgbẹgbàárún” ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?”