6 Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti pa Fílístínì, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Ísírẹ́lì wá láti pàdé ọba Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tamborínì àti ohun èlò orin.
7 Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé:“Ṣọ́ọ̀lù pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀Dáfídì sì pa ẹgbẹgbàárún ní tirẹ̀.”
8 Ṣọ́ọ̀lù sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dáfídì pẹ̀lú ẹgbẹgbàárún” ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?”
9 Lati ìgbà náà lọ ni Ṣọ́ọ̀lù ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlára wo Dáfídì.
10 Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Ṣọ́ọ̀lù, ó sì sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dáfídì sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀.
11 Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dáfídì pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dáfídì yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.
12 Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ̀rù Dáfídì nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì, ṣùgbọ́n ó ti fi Ṣọ́ọ̀lù sílẹ̀.