3 “Má ṣe halẹ̀;má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jádenítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.
4 “Ọrun àwọn alágbára ti ṣẹ́,àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.
5 Àwọn tí ó yọ̀ fún òunjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní: tóbẹ́ẹ̀ ti àgàn fi bí méje.Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.
6 “Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà-òkú, ó sì gbé dìde.
7 Olúwa sọ di talákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.
8 Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,ó gbé alágbe sókè láti orí òkítì eérú wá,láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,láti mu wọn jogún ìtẹ́ ogo:“Nítorí pé ọ̀wọ̀n ayé ti Olúwa ni,ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
9 Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.