1 Nígbà náà ni Dáfídì sá kúrò ní Naíótì ti Rámà ó sì lọ sọ́dọ̀ Jónátanì ó sì béèrè pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Báwo ni mo ṣe ṣẹ baba rẹ, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi?”
2 Jónátanì dáhùn pé, “Kí a má rí i! Ìwọ kò ní kú! Wò ó baba mi kì í ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí tí ó kéré, láì fi lọ̀ mí. Èéṣe tí yóò fi fi èyí pamọ́ fún mi? Kò rí bẹ́ẹ̀.”
3 Ṣùgbọ́n Dáfídì tún búra, ó sì wí pé, “Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojú rere ní ojú ù rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Jónátanì kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́.’ Ṣíbẹ̀ nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láàyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrin èmi àti ikú.”
4 Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe, èmi yóò ṣe é fún ọ.”
5 Dáfídì wí pé, “Wò ó, ọ̀la ni oṣù tuntun, mo sì gbọdọ́ bá ọba jẹun, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó lọ láti fi ara pamọ́ lórí pápá títí di àṣálẹ́ ọjọ́ kẹta.
6 Tí baba rẹ bá fẹ́ mi kù, sọ fún un pé, ‘Dáfídì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀.’
7 Tí o bá wí pé, ‘Ó dára náà,’ nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ wà láìléwu. Ṣùgbọ́n tí ó bá bínú gidigidi, ìwọ yóò mọ̀ dájú pé ó pinnu láti ṣe ìpalára mi.