1 Sámúẹ́lì 20:3-9 BMY

3 Ṣùgbọ́n Dáfídì tún búra, ó sì wí pé, “Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojú rere ní ojú ù rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Jónátanì kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́.’ Ṣíbẹ̀ nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láàyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrin èmi àti ikú.”

4 Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe, èmi yóò ṣe é fún ọ.”

5 Dáfídì wí pé, “Wò ó, ọ̀la ni oṣù tuntun, mo sì gbọdọ́ bá ọba jẹun, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó lọ láti fi ara pamọ́ lórí pápá títí di àṣálẹ́ ọjọ́ kẹta.

6 Tí baba rẹ bá fẹ́ mi kù, sọ fún un pé, ‘Dáfídì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀.’

7 Tí o bá wí pé, ‘Ó dára náà,’ nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ wà láìléwu. Ṣùgbọ́n tí ó bá bínú gidigidi, ìwọ yóò mọ̀ dájú pé ó pinnu láti ṣe ìpalára mi.

8 Ṣùgbọ́n ní tirẹ ìwọ, fi ojú rere wo ìránṣẹ́ rẹ; nítorí tí ìwọ ti báa dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ níwájú Olúwa. Tí mo bá jẹ̀bi, pa mí fún ara rẹ! Èéṣe tí ìwọ yóò fi fi mí lé baba rẹ lọ́wọ́?”

9 Jónátanì wí pé, “Kí a má ríi! Ti mo bá ti gbọ́ tí baba mi ti pinnu láti pa ọ́ lára, ṣé èmi kò ní sọ fún ọ?”