24 Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Ṣọ́ọ̀lù lọ sí Sífì: ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní ihà Máónì, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúsù ti Jésímónì.
25 Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dáfídì: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní ihà ti Máónì. Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́, ó sì lépa Dáfídì ní ihà Máónì.
26 Ṣọ́ọ̀lù sì ń rin apákan òkè kan, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apákejì òkè náà. Dáfídì sì yára láti sá kúrò níwájú Ṣọ́ọ̀lù; nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn.
27 Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Fílístínì ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.”
28 Ṣọ́ọ̀lù sì padà kúrò ní lilépa Dáfídì, ó sì lọ pàdé àwọn Fílístínì nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní òkúta ìpínyà.
29 Dáfídì sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sápamọ́ sí ní Éńgédì.