22 Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Bélíálì nínú àwọn tí o bá Dáfídì lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.”
23 Dáfídì sì wí pé, “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi: Olúwa ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́-ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́.
24 Ta ni yóò gbọ́ tiyín nínú ọran yìí? Ṣùgbọ́n bi ìpín ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ si ìjà ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ti ó dúró ti ẹrù; wọn ó sì pín in bákan náà.”
25 Lati ọjọ́ náà lọ, ó sì pàṣẹ, ó sì sọ ọ di òfin fún Ísírẹlì títí di òní yìí.
26 Dáfídì sì padà sí Síkílágì, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbà Júdà, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀ta Olúwa wa.”
27 Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Bẹ́tẹ́lì àti sí àwọn tí ó wà ní Gúúsù tí Rámótì, àti sí àwọn tí ó wà ní Játírì.
28 Àti sí àwọn tí ó wà ní Áróérì, àti sí àwọn tí ó wà ní Sífímótì, àti sí àwọn tí ó wà ni Ésítémóà.