1 Ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì tọ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá.Nísinsìnyìí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde láti lọ bá àwọn Fílístínì jà. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pàgọ́ sí Ebenésérì àti àwọn Fílístínì ní Áfékì.
2 Àwọn Fílístínì mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Ísírẹ́lì, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Fílístínì ṣẹ́gun Ísírẹ́lì wọ́n pa ẹgbàájì ọkùnrin nínú ogun náà (4,000).
3 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbà Ísírẹ́lì sì béèrè pé, “Èéṣe ti Olúwa fi mú kí àwọn Fílístínì ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti Ṣílò wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbàwá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wa.”
4 Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣílò, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn ọmọ ogun wá, ẹni tí ń wà láàrin àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Élì méjèèjì Hófínì àti Fínéhásì wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.