19 Aya ọmọ rẹ̀, ìyàwó Fínéhásì, ó lóyún ó súnmọ́ àkókò àti bí. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn náà wí pé wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ àti wí pé baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó rọbí ó sì bímọ, ó sì borí ìrora ìrọbí náà.
20 Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, “má ṣe bẹ̀rù; nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin.” Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i.
21 Ó sì pe ọmọ náà ní Íkábódù, wí pé, “Kò sí ògo fún Ísírẹ́lì mọ́” nítorí tí wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àti ikú baba ọkọ rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀.
22 Ó si wí pé, “Ogo kò sí fún Isirẹli mọ́, nítorí ti a ti gbá àpótí Ọlọ́run”