1 Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Fílístínì ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebenésérì sí Ásídódù.
2 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí náà lọ sí Tẹ́ḿpìlì Dágónì, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ Dágónì.
3 Nígbà tí àwọn ará Ásídódù jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dágónì ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dágónì, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀.
4 Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dágónì sì wá, ó ṣubú ó dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.
5 Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dágónì tàbí àwọn mìíràn tí ó wo inú tẹ́ḿpìlì Dágónì ní Ásídódù fi ń tẹ orí ìloro ẹnu ọ̀nà.
6 Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Ásídódù àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú àrùn oníkókó.