1 Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Fílístínì fún oṣù méje,
2 àwọn ará Fílístínì pe àwọn àlùfáà, àti àwọn aláṣọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí àyè rẹ̀.”
3 Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Olúwa ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.”
4 Àwọn ará Fílístínì béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?”Wọ́n dáhùn, “Góòlù oníkókó márùn ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn ún, gẹ́gẹ́ bí iye awọn aláṣẹ Fílístínì, nítorí àjàkálẹ̀-àrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín.
5 Mọ àwòrán àrùn oníkókó àti ti eku èlírí yin tí ó ń ba orílẹ̀ èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín.