1 Ará Bẹ́ńjámínì kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíṣì, ọmọ Ábíélì, ọmọ Sésórì, ọmọ Békórátì, ọmọ Áfíà ti Bẹ́ńjámínì.
2 Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Ṣọ́ọ̀lù, ọ̀dọ̀mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàárin gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì—láti èjìka rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga jú gbogbo àwọn ènìyàn tó kù lọ.
3 Nísinsìn yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù sì sọnù. Nígbà náà, Kíṣì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”
4 Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrin àwọn ìlú olókè Éfúráímù, ó sì kọja ní àyíká ilẹ̀ Sálísà, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Sálímù, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Bẹ́ńjámínì, wọn kò sì rí wọn.
5 Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Ṣúfù, Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.”