1 Sámúẹ́lì 9:15-21 BMY

15 Olúwa ti sọ létí Sámúẹ́lì ní ijọ́ kan kí Ṣọ́ọ̀lù ó tó dé pé,

16 “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

17 Nígbà tí Sámúẹ́lì fojú rí Ṣọ́ọ̀lù, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”

18 Ṣọ́ọ̀lù sì súnmọ́ Sámúẹ́lì ní ẹnu ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, “Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà.”

19 Sámúẹ́lì dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ.

20 Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dàamú nípa wọ́n: a ti rí wọn. Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Ísírẹ́lì wà? Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ.”

21 Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há à ṣe ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Kékeré nínú ẹ̀yá Ísírẹ́lì: Ìdílé mi kò há rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹyà Bẹ́ńjámínì? Èésì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?”