1 Ní àkókò náà ni Jésù ń la àárin oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́.
2 Nígbà tí àwọn Farisí rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”
3 Jésù dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dáfídì se nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
4 Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò se fún àwọn àlùfáà nìkan.
5 Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹ́ḿpílì ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láì jẹ̀bi.
6 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹ́ńpílì lọ wà níhìn-ín.