14 Ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”
15 Pétérù wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”
16 Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èé ha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”?
17 “Ìwọ kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde?
18 Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’
19 Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpanìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.
20 Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ ”