14 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Jòhánù onítẹ̀bọ́mì ni, àwọn mìíràn wí pé, Èlíjà ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremáyà ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”
15 “Ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ìwọ rò pé mo jẹ́?”
16 Símónì Pétérù dáhùn pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè”
17 Jésù sì wí fún un pé, “Alábùnkún-fún ni ìwọ Símónì ọmọ Jónà, nítorí ènìyàn kọ́ ló fi èyí hàn bí kò se Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.
18 Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Pétérù àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò-òkú kì yóò lè borí rẹ̀.
19 Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhùn tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.”
20 Nígbà náà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kírísítì náà.