19 Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhùn tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.”
20 Nígbà náà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kírísítì náà.
21 Láti ìgbà yìí lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí iṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerúsálémù láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn, olórí àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, pé wọn yóò pa òun, àti pé òun yóò jí dìde sí ààyè ní ọjọ́ kẹ́ta.
22 Pétérù mú Jésù sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, “Kí a má rí i Olúwa. Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ.”
23 Jésù pa ojú dà, ó sì wí fún Pétérú pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Sàtáni! Ohun ìkọ̀ṣẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ kò ro ohun tí i se ti Ọlọ́run, bí kò se èyí ti se ti ènìyàn.”
24 Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.
25 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóò rí i.