24 Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.
25 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóò rí i.
26 Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀?
27 Nítorí Ọmọ ènìyàn yóò wá nínú ogo baba rẹ pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
28 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹlòmíràn wà nínú àwọn tí ó níhìn-ín yìí, tí kì yóò ri ikú títí wọn ó fi rí ọmọ-ènìyàn tí yóò máa bà ní ìjọba rẹ̀.”