1 Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó tóbi jùlọ ní ìjọba ọ̀run?”
2 Jésù sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrin wọn.
3 Ó wí pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run.
4 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run.
5 “Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí.
6 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọkékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi òkun.
7 “Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípaṣẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá!