15 Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.
16 Ẹnì kan sì wá ó bí Jésù pé, “Olùkọ́, ohun rere wo ni èmi yóò ṣe kí n tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”
17 Jésù dá a lóhùn pé, “È é ṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”
18 Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jésù dáhùn pé, “ ‘Má ṣe pànìyàn, má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe ìjẹ̀rìí èké,
19 bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. Kí o sì fẹ́ aládúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”
20 Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi mo ní láti ṣe?”
21 Jésù wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”