17 Nísinsìn yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó-orí fún Késárì tàbí kò tọ́?”
18 Ṣùgbọ́n Jésù ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, è é se ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò?
19 Ẹ fi owo ẹyọ tí a fi ń san owo-orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un,
20 ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán tabi èyí? Àkọlé tà sì ní?”
21 Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Késárì ni.”“Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Késárì fún Késárì, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
22 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnú yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
23 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusí tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jésù wá láti bi í ní ìbéèrè pé,