21 Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Késárì ni.”“Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Késárì fún Késárì, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
22 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnú yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
23 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusí tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jésù wá láti bi í ní ìbéèrè pé,
24 Wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mósè wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ sú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un.
25 Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrin wa níhìn-in yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú láìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì.
26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ. A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e. Bẹ́ẹ̀ sì ni títítí òun fi di ìyàwó ẹnì kéje.
27 Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú.