17 Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè talẹ́ntì méjì mìíràn.
18 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀.
19 “Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀. Ó pè wọ́n jọ láti bá wọn sírò owó rẹ̀.
20 Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’
21 “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́: ìwọ ṣe olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’
22 “Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ńtì méjì mìíràn.’
23 “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’