13 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìyìn rere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”
14 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn àpósítélì méjìlá ti à ń pè ní Júdásì Ìskáríọ́tù lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.
15 Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jésù lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á.
16 Láti ìgbà náà lọ ni Júdásì ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.
17 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àkàrà àìwú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jésù wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?”
18 Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ”
19 Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀.