26 Nígbà náà ni Pílátù dá Bárábà sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jésù tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.
27 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun baálẹ̀ mú Jésù lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í
28 Wọ́n tú Jésù sì ìhòòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ láṣọ òdòdó,
29 Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù!”
30 Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án mọ́ ọn lórí.
31 Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
32 Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kíréné tí à ń pè ní Símónì. Wọ́n sì mú ọkùnn náà ní túlààsì láti ru àgbélébùú Jésù.