35 Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn.
36 Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀.
37 Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé: “ÈYÍ NI JÉSÙ, ỌBA ÀWỌN JÚÙ” síbẹ̀.
38 Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀.
39 Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé:
40 “Ìwọ tí yóò wó tẹ́ḿpìlì, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ-Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀ kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”
41 Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà.