14 Bí Baálẹ̀ bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.”
15 Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrin àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí.
16 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Gálílì ní orí òkè níbi tí Jésù sọ pé wọn yóò ti rí òun.
17 Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n forí balẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyè méjì bóyá Jésù ni tàbí òun kọ́.
18 Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi.
19 Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ máa kọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitíísì wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́.
20 Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsí ohun gbogbo èyí tí mo ti pa láṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”