5 Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerúsálémù àti gbogbo Jùdíà àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jọ́dánì.
6 Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó ṣe í ìtẹ̀bọmi fún wọn nínú odò Jọ́dánì ibi tí ó ti ń se.
7 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisí àti Sadúsì tí wọ́n ń wá si ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ibínú Ọlọ́run tí ń bọ̀?
8 Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònú-pìwàdà.
9 Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Ábúráhámù ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Ábúráhámù.
10 Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò gé lulẹ̀ ti a ó sì jù wọn sínú iná.
11 “Èmi fi omi bamitíìsì yín fún ìrónúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitíìsì yín.