18 Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, àmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé ofin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ.
19 Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jù lọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jù lọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sewọn, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run.
20 Nítorì náà ni mọ ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisí àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.
21 “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’
22 Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arakùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà’ yóò fara hàn níwájú Sahẹ́ńdìrì; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.
23 “Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá ṣíwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ.
24 Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrin ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀.