22 OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.
23 Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.
24 Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.
25 Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.
26 Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi,ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà.
27 Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé,ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
28 Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà,kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.