15 Àwọn ni wọ́n la odò Jọdani kọjá ninu oṣù kinni, ní àkókò ìgbà tí ó kún bo bèbè rẹ̀, wọ́n sì ṣẹgun gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, ní apá ìhà ìlà oòrùn ati apá ìwọ̀ oòrùn.
16 Àwọn kan láti inú ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Bẹnjamini wá sọ́dọ̀ Dafidi níbi ààbò.
17 Dafidi lọ pàdé wọn, ó ní, “Tí ẹ bá wá láti darapọ̀ mọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́, ati láti ràn mí lọ́wọ́, inú mi dùn sí yín; ṣugbọn bí ẹ bá wá ṣe amí fún àwọn ọ̀tá mi, nígbà tí ó ti jẹ́ pé n kò ní ẹ̀bi, Ọlọrun àwọn baba wa rí yín, yóo sì jẹ yín níyà.”
18 Ẹ̀mí Ọlọrun bá bà lé Amasai, olórí àwọn ọgbọ̀n ọmọ ogun olókìkí, ó bá dáhùn pé,“Tìrẹ ni wá, Dafidi;a sì wà pẹlu rẹ, ọmọ Jese!Alaafia, alaafia ni fún ọ,alaafia sì ni fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ!Nítorí pé Ọlọrun rẹ ń ràn ọ́ lọ́wọ́.”Dafidi bá gbà wọ́n, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
19 Àwọn kan ninu ẹ̀yà Manase darapọ̀ mọ́ Dafidi nígbà tí òun pẹlu àwọn ará Filistia wá láti bá Saulu jagun. (Sibẹsibẹ kò lè ran àwọn Filistia lọ́wọ́, nítorí pé lẹ́yìn tí àwọn ọba àwọn Filistini jíròrò láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ewu ń bẹ nítorí pé yóo darapọ̀ pẹlu Saulu, ọ̀gá rẹ̀.”) Wọ́n bá dá a pada lọ sí Sikilagi.
20 Bí ó ti ń pada lọ sí Sikilagi, àwọn ará Manase kan wá, wọ́n bá darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi. Orúkọ wọn ni: Adina, Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli; Josabadi, Elihu ati Siletai, olórí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ ogun ninu ẹ̀yà Manase.
21 Wọ́n ran Dafidi lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, wọ́n sì jẹ́ ọ̀gágun.