1 Adamu bí Seti, Seti bí Enọṣi.
2 Enọṣi bí Kenaani, Kenaani bí Mahalaleli, Mahalaleli bí Jaredi;
3 Jaredi bí Enọku, Enọku bí Metusela, Metusela bí Lamẹki;
4 Lamẹki bí Noa, Noa bí Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti.
5 Àwọn ọmọ Jafẹti ni Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi.
6 Gomeri ni baba ńlá àwọn ọmọ Aṣikenasi, Difati ati Togama.
7 Jafani ni baba ńlá àwọn ọmọ Eliṣa, Taṣiṣi, ati àwọn ará Kitimu, ati Rodọni.
8 Hamu ni baba Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani,
9 Kuṣi bí Ṣeba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka; Raama ni baba Ṣeba ati Dedani,
10 Kuṣi bí Nimrodu. Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí ó di akikanju ati alágbára lórí ilẹ̀ ayé.
11 Ijipti ni baba àwọn ará Lidia ati ti Anamu, ti Lehabu, ati ti Nafitu;
12 àwọn ará Patirusimu ati ti Kasilu tíí ṣe baba ńlá àwọn ará Filistia ati àwọn ará Kafito.
13 Àkọ́bí Kenaani ní Sidoni, lẹ́yìn rẹ̀ ó bí Heti,
14 Kenaani yìí náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Girigaṣi;
15 àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki ati àwọn ará Sini;
16 àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari ati àwọn ará Hamati.
17 Ṣemu ni baba Elamu, Aṣuri, ati Apakiṣadi, Ludi, Aramu, ati Usi, Huli, Geteri ati Meṣeki.
18 Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela ni baba Eberi,
19 Eberi bí ọmọkunrin meji: Ekinni ń jẹ́ Pelegi, (nítorí pé ní àkókò tirẹ̀ ni àwọn eniyan ayé pín sí meji); ọmọ Eberi keji sì ń jẹ́ Jokitani,
20 Jokitani ni ó bí Alimodadi, Ṣelefu, Hasarimafeti, ati Jera;
21 Hadoramu, Usali, ati Dikila;
22 Ebali, Abimaeli, ati Ṣeba,
23 Ofiri, Hafila ati Jobabu; Àwọn ni àwọn ọmọ Jokitani.
24 Arọmọdọmọ Ṣemu títí fi dé orí Abramu nìyí: Ṣemu, Apakiṣadi, Ṣela;
25 Eberi, Pelegi, Reu;
26 Serugi, Nahori, Tẹra;
27 Abramu, tí a tún ń pè ní Abrahamu.
28 Àwọn ọmọ Abrahamu ni Isaaki ati Iṣimaeli.
29 Àkọsílẹ̀ ìran wọn nìyí: Nebaiotu ni àkọ́bí Iṣimaeli, lẹ́yìn náà ni ó bí Kedari, Adibeeli, ati Mibisamu;
30 Miṣima, Duma ati Masa; Hadadi ati Tema;
31 Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema.
32 Abrahamu ní obinrin kan tí ń jẹ́ Ketura. Ó bí àwọn ọmọ mẹfa wọnyi fún Abrahamu: Simirani, Jokiṣani ati Medani; Midiani, Iṣibaki ati Ṣua. Àwọn ọmọ ti Jokiṣani ni: Ṣeba ati Dedani.
33 Àwọn ọmọ marun-un tí Midiani bí ni Efa, Eferi ati Hanoku, Abida ati Elidaa. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Ketura.
34 Abrahamu ni baba Isaaki. Àwọn ọmọ Isaaki meji ni Esau ati Jakọbu.
35 Àwọn ọmọ Esau ni Elifasi, Reueli, ati Jeuṣi; Jalamu ati Kora.
36 Àwọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari ati Sefi; Gatamu, Kenasi, Timna ati Amaleki.
37 Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama ati Misa.
38 Àwọn ọmọ Seiri ni Lotani, Ṣobali ati Sibeoni; Ana, Diṣoni, Eseri ati Diṣani.
39 Àwọn ọmọ Lotani ni Hori ati Homami. Lotani ní arabinrin kan tí ń jẹ́ Timna.
40 Àwọn ọmọ Ṣobali ni Aliani, Manahati ati Ebali; Ṣefi ati Onamu. Sibeoni ni baba Aia ati Ana.
41 Ana ni baba Diṣoni. Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hamirani, Eṣibani, Itirani ati Kerani.
42 Eseri ló bí Bilihani, Saafani ati Jaakani. Diṣani ni baba Usi ati Arani.
43 Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu, kí ọba kankan tó jẹ ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: Bela, ọmọ Beori; orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.
44 Nígbà tí Bela kú, Jobabu, ọmọ Sera, ará Bosara, jọba tẹ̀lé e.
45 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu, ará ìlú kan ní agbègbè Temani, jọba tẹ̀lé e.
46 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun àwọn ará Midiani ní ilẹ̀ Moabu, jọba tẹ̀lé e. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.
47 Nígbà tí Hadadi kú, Samila ará Masireka, jọba tẹ̀lé e.
48 Nígbà tí Samila kú, Ṣaulu ará Rehoboti létí odò Yufurate, jọba tẹ̀lé e.
49 Nígbà tí Ṣaulu kú, Baali Hanani, ọmọ Akibori, jọba tẹ̀lé e.
50 Nígbà tí Baali Hanani kú, Hadadi, jọba tẹ̀lé e. Ìlú tirẹ̀ ni Pau. Iyawo rẹ̀ ni Mehetabeli, ọmọ Matiredi, ìyá rẹ̀ àgbà ni Mesahabu. Nígbà tí ó yá, Hadadi náà kú.
51 Àwọn ìjòyè ẹ̀yà Edomu nìwọ̀nyí: Timna, Alia, ati Jeteti;
52 Oholibama, Ela, ati Pinoni,
53 Kenasi, Temani, ati Mibisari,
54 Magidieli ati Iramu.