1 Nígbà tí Dafidi dàgbà, tí ó di arúgbó, ó fi Solomoni, ọmọ rẹ̀ jọba lórí Israẹli.
2 Dafidi pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn alufaa ati àwọn Lefi jọ.
3 Ó ka gbogbo àwọn Lefi tí wọ́n jẹ́ ọkunrin tí wọ́n dàgbà tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún sókè, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa mọkandinlogun (38,000).
4 Dafidi fún ẹgbaa mejila (24,000) ninu wọn ní iṣẹ́ ninu tẹmpili; ó ní kí ẹgbaata (6,000) máa ṣe àkọsílẹ̀ ati ìdájọ́ àwọn eniyan,
5 kí ẹgbaaji (4,000) máa ṣọ́nà, kí ẹgbaaji (4,000) sì máa yin OLUWA pẹlu oríṣìíríṣìí ohun èlò orin tí ọba pèsè.
6 Dafidi pín àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé ìdílé: ti Geriṣomu, ti Kohati, ati ti Merari.
7 Àwọn ọmọ Geriṣomu jẹ́ meji: Ladani ati Ṣimei;
8 Àwọn ọmọ Ladani jẹ́ mẹta: Jeieli tí ó jẹ́ olórí, Setamu ati Joẹli.
9 Àwọn ọmọ Ṣimei ni Ṣelomoti, Hasieli, ati Harani; àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí ìdílé Ladani.
10 Àwọn ọmọ Ṣimei jẹ́ mẹrin: Jahati, Sina, Jeuṣi, ati Beraya.
11 Jahati ni ó jẹ́ olórí, Sisa ni igbákejì rẹ̀, ṣugbọn Jeuṣi ati Beraya kò bí ọmọ pupọ, nítorí náà ni wọ́n fi kà wọ́n sí ìdílé kan ninu ọ̀kan ninu àwọn àkọsílẹ̀.
12 Àwọn ọmọ Kohati jẹ́ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli,
13 Àwọn ọmọ Amramu ni Aaroni ati Mose. Aaroni ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, pé kí òun ati àwọn ìran rẹ̀ títí lae máa sun turari níwájú OLUWA, kí wọ́n máa darí ìsìn OLUWA, kí wọ́n sì máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ rẹ̀ títí lae.
14 A ka àwọn ọmọ Mose, iranṣẹ Ọlọrun, pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà Lefi.
15 Mose bí ọmọkunrin meji: Geriṣomu ati Elieseri.
16 Àwọn ọmọ Geriṣomu ni: Ṣebueli, olórí ìdílé Geriṣomu.
17 Elieseri bí ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Rehabaya, olórí ìdílé rẹ̀, kò sì bí ọmọ mìíràn mọ́, ṣugbọn àwọn ọmọ Rehabaya pọ̀.
18 Iṣari bí ọmọkunrin kan, Ṣelomiti, tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀.
19 Heburoni bí ọmọ mẹrin: Jeraya, tí ó jẹ́ olórí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Amaraya, Jahasieli, Jekameamu.
20 Usieli bí ọmọ meji: Mika, tí ó jẹ́ olórí, ati Iṣaya.
21 Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Mahili bí ọmọkunrin meji: Eleasari ati Kiṣi,
22 Ṣugbọn Eleasari kú láì ní ọmọkunrin kankan; kìkì ọmọbinrin ni ó bí. Àwọn ọmọbinrin rẹ̀ bá fẹ́ àwọn ọmọ Kiṣi, àbúrò baba wọn.
23 Àwọn ọmọ Muṣi jẹ́ mẹta: Mahili, Ederi ati Jeremotu.
24 Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.
25 Dafidi ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi, yóo sì máa gbé Jerusalẹmu títí lae.
26 Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.”
27 Gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi ti ṣe, iye àwọn ọmọ Lefi láti ogún ọdún sókè nìyí:
28 Ṣugbọn iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, láti máa ṣe ìtọ́jú àgbàlá ati àwọn yàrá ibẹ̀, láti rí i pé àwọn ohun èlò ilé OLUWA wà ní mímọ́, ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó yẹ ninu ilé OLUWA.
29 Àwọn ni wọ́n tún ń ṣe ètò ṣíṣe burẹdi ìfihàn, ìyẹ̀fun fún ẹbọ ohun jíjẹ, àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ninu, àkàrà díndín fún ẹbọ, ẹbọ tí a po òróró mọ́, ati pípèsè àwọn oríṣìíríṣìí ìwọ̀n.
30 Wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA ní àràárọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́,
31 ati nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń rúbọ sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ oṣù titun, tabi ọjọ́ àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí a yàn láti máa kọrin níwájú OLUWA nígbà gbogbo.
32 Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa bojútó Àgọ́ Àjọ ati ibi mímọ́, tí wọn yóo sì máa ran àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́, níbi iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA.