Kronika Kinni 2 BM

Àwọn Arọmọdọmọ Juda

1 Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni;

2 Dani, Josẹfu, ati Bẹnjamini; Nafutali, Gadi ati Aṣeri.

3 Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á.

4 Tamari, iyawo ọmọ Juda, bí ọmọ meji fún un: Peresi ati Sera.

5 Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli.

6 Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada.

7 Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀.

8 Etani ni ó bí Asaraya.

Ìran Dafidi Ọba

9 Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai.

10 Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda,

11 Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi,

12 Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese.

13 Jese bí ọmọ meje; orúkọ wọn nìyí bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Eliabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Abinadabu ati Ṣimea;

14 Netaneli ati Radai;

15 Osemu ati Dafidi.

16 Àwọn arabinrin wọn ni Seruaya ati Abigaili. Seruaya yìí ló bí Abiṣai, Joabu ati Asaheli.

17 Abigaili fẹ́ Jeteri láti inú ìran Iṣimaeli, ó sì bí Amasa fún un.

Ìran Hesironi

18 Hesironi ni baba Kalebu. Asuba (ati Jeriotu) ni aya Kalebu yìí, Asuba bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeseri, Ṣobabu, ati Aridoni.

19 Nígbà tí Asuba kú, Kalebu fẹ́ Efurati, Efurati sì bí Huri fún un.

20 Huri ni ó bí Uri, Uri sì bí Besaleli.

21 Nígbà tí Hesironi di ẹni ọgọta ọdún, ó fẹ́ ọmọbinrin Makiri, baba Gileadi. Ọmọbinrin yìí sì bí ọmọkunrin kan fún un tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Segubu.

22 Segubu ni ó bí Jairi, tí ó jọba lórí ìlú ńláńlá mẹtalelogun ní ilẹ̀ Gileadi.

23 Ṣugbọn Geṣuri ati Aramu gba Hafoti Jairi lọ́wọ́ rẹ̀, ati Kenati ati àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká rẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Makiri, baba Gileadi.

24 Lẹ́yìn ìgbà tí Hesironi kú, Kalebu ṣú Efurata, iyawo baba rẹ̀ lópó, ó sì bí Aṣuri, tíí ṣe baba Tekoa.

Àwọn Ìran Jerameeli

25 Jerameeli, àkọ́bí Hesironi, bí ọmọkunrin marun-un: Ramu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Buna, Oreni, Osemu, ati Ahija.

26 Jerameeli tún ní aya mìíràn, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara, òun ni ìyá Onamu.

27 Àwọn ọmọ Ramu, àkọ́bí Jerameeli ni: Maasi, Jamini ati Ekeri.

28 Onamu bí ọmọ meji: Ṣamai ati Jada. Ṣamai náà bí ọmọ meji: Nadabu ati Abiṣuri.

29 Orúkọ aya Abiṣuri ni Abihaili, ó sì bí Ahibani ati Molidi fún un.

30 Nadabu, arakunrin Abiṣuri náà bí ọmọ meji: Seledi ati Apaimu; ṣugbọn Seledi kò bímọ títí tí ó fi kú.

31 Apaimu ni baba Iṣi. Iṣi bí Ṣeṣani, Ṣeṣani sì bí Ahilai.

32 Jada, arakunrin Ṣamai, bí ọmọ meji: Jeteri ati Jonatani, ṣugbọn Jeteri kò bímọ títí tí ó fi kú.

33 Jonatani bí ọmọ meji: Peleti ati Sasa. Àwọn ni ìran Jerameeli.

34 Ṣeṣani kò bí ọmọkunrin kankan, kìkì ọmọbinrin ni ó bí; ṣugbọn Ṣeṣani ní ẹrú kan, ará Ijipti, tí ń jẹ́ Jariha.

35 Ṣeṣani fi ọmọ rẹ̀ obinrin fún Jariha, ẹrú rẹ̀, ó sì bí Atai fún ẹrú náà.

36 Atai ni baba Natani, Natani sì ni baba Sabadi.

37 Sabadi bí Efiali, Efiali sì bí Obedi.

38 Obedi ni baba Jehu, Jehu sì ni baba Asaraya.

39 Asaraya ni ó bí Helesi, Helesi ni ó sì bí Eleasa.

40 Eleasa bí Sisimai, Sisimai bí Ṣalumu;

41 Ṣalumu bí Jekamaya, Jekamaya sì bí Eliṣama.

Àwọn Ìran Kalebu Yòókù

42 Àwọn ọmọ Kalebu, arakunrin Jerameeli, nìwọ̀nyí: Mareṣa, baba Sifi ni àkọ́bí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó bí Heburoni.

43 Heburoni bí ọmọ mẹrin: Kora, Tapua, Rekemu ati Ṣema.

44 Ṣema bí Rahamu, Rahamu bí Jokeamu, Rekemu sì bí Ṣamai.

45 Ṣamai ló bí Maoni, Maoni sì bí Betisuri.

46 Kalebu tún ní obinrin kan tí ń jẹ́ Efa, ó bí ọmọ mẹta fún un: Harani, Mosa ati Gasesi. Harani bí ọmọ kan tí ń jẹ́ Gasesi.

47 Àwọn ọmọ Jadai nìwọ̀nyí: Regemu, Jotamu, ati Geṣani, Peleti, Efa ati Ṣaafu.

48 Kalebu tún ní obinrin mìíràn tí ń jẹ́ Maaka. Ó bí ọmọ meji fún un: Ṣeberi ati Tirihana.

49 Maaka yìí kan náà ni ó bí Ṣaafu, baba Madimana, tí ó tẹ ìlú Madimana dó, ati Ṣefa, baba Makibena ati Gibea, àwọn ni wọ́n tẹ ìlú Makibena ati ìlú Gibea dó.Kalebu tún bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Akisa.

50 Àwọn ìran Kalebu yòókù ni: àwọn ọmọ Huri àkọ́bí Efurata, iyawo Kalebu: ati Ṣobali, baba Kiriati Jearimu;

51 Salima, baba Bẹtilẹhẹmu, ati Harefu baba Betigaderi.

52 Ṣobali baba Kiriati Jearimu ni baba gbogbo àwọn ará Haroe, ati ìdajì àwọn tí ń gbé Menuhotu,

53 Òun náà ni baba ńlá gbogbo àwọn ìdílé tí ń gbé Kiriati Jearimu, àwọn ìdílé bíi Itiri, Puti, Ṣumati, ati Miṣirai; lára wọn ni àwọn tí wọn ń gbé ìlú Sora ati Eṣitaolu ti ṣẹ̀.

54 Salima ni baba àwọn ará Bẹtilẹhẹmu, Netofati, ati ti Atirotu Beti Joabu; àwọn ará Soriti ati ìdajì àwọn ará Manahati.

55 Àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé tí wọn ń gbé Jabesi nìyí: àwọn ará Tirati, Ṣimeati, ati Sukati. Àwọn ni ará Keni tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Hamati baba ńlá wọn ní ilé Rekabu.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29