1 Àwọn mẹrin ni ọmọ Isakari: Tola, Pua, Jaṣubu ati Ṣimironi.
2 Àwọn ọmọ Tola ni: Usi, Refaaya, Jerieli, Jahimai, Ibisamu ati Ṣemueli, àwọn ni baálé ninu ìdílé Tola, baba wọn, akikanju jagunjagun ni wọ́n ní àkókò wọn. Ní ayé Dafidi ọba, àwọn akikanju jagunjagun wọnyi jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹta (22,600).
3 Usi ni ó bí Isiraya. Isiraya sì bí ọmọ mẹrin: Mikaeli, Ọbadaya, Joẹli, ati Iṣaya; wọ́n di marun-un, àwọn maraarun ni wọ́n sì jẹ́ ìjòyè.
4 Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé ìdílé, àwọn jagunjagun tí wọ́n ní tó ẹgbaa mejidinlogun (36,000) kún ara wọn, ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí; nítorí wọ́n ní ọpọlọpọ iyawo ati ọmọ.
5 Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu àwọn ìbátan wọn ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogoji ó lé ẹgbẹrun (87,000).
6 Àwọn mẹta ni ọmọ Bẹnjamini: Bela, Bekeri, ati Jediaeli.
7 Bela bí ọmọ marun-un: Esiboni, Usi, Usieli, Jerimotu ati Iri. Àwọn ni baálé ìdílé wọn, wọ́n sì jẹ́ akọni jagunjagun. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu ìdílé wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ati mẹrinlelọgbọn (22,034).
8 Bekeri bí ọmọ mẹsan-an: Semira, Joaṣi, ati Elieseri; Elioenai, Omiri, ati Jeremotu; Abija, Anatoti, ati Alemeti.
9 Àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé, àwọn baálé baálé ní ilé baba wọn, tí wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati igba (20,200).
10 Jediaeli ni baba Bilihani; Bilihani bí ọmọ meje: Jeuṣi, Bẹnjamini, Ehudu, Kenaana, Setani, Taṣiṣi ati Ahiṣahari.
11 Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jediaeli; àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé ní ilé baba wọn ati akọni jagunjagun ninu ìran wọn tó ẹẹdẹgbaasan-an ó lé igba (17,200).
12 Ṣupimu ati Hupimu jẹ́ ọmọ Iri, ọmọ Aheri sì ni Huṣimu.
13 Nafutali bí ọmọ mẹrin: Jasieli, Guni, Jeseri, ati Ṣalumu. Biliha ni ìyá baba wọn.
14 Manase fẹ́ obinrin kan, ará Aramea; ọmọ meji ni obinrin náà bí fún un; Asirieli, ati Makiri, baba Gileadi.
15 Makiri fẹ́ iyawo kan ará Hupi, ati ọ̀kan ará Ṣupimu. Orúkọ arabinrin rẹ̀ ni Maaka. Orúkọ ọmọ rẹ̀ keji ni Selofehadi; tí gbogbo ọmọ tirẹ̀ jẹ́ kìkì obinrin.
16 Maaka, Iyawo Makiri, bí ọmọ meji: Pereṣi ati Ṣereṣi. Ṣereṣi ni ó bí Ulamu ati Rakemu;
17 Ulamu sì bí Bedani. Àwọn ni ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase.
18 Arabinrin Gileadi kan tí ń jẹ́ Hamoleketu ni ó bí Iṣodu, Abieseri, ati Mahila.
19 Ṣemida bí ọmọkunrin mẹrin: Ahiani, Ṣekemu, Liki, ati Aniamu.
20 Àwọn arọmọdọmọ Efuraimu nìwọ̀nyí: Ṣutela ni baba Beredi, baba Tahati, baba Eleada, baba Tahati,
21 baba Sabadi, baba Ṣutela, Eseri, ati Eleadi; Eseri ati Eleadi yìí ni àwọn ará ìlú Gati pa nígbà tí wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn àwọn ará Gati.
22 Baba wọn, Efuraimu, ṣọ̀fọ̀ wọn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá wá láti tù ú ninu.
23 Lẹ́yìn náà, Efuraimu bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọmọ náà ní Beraya nítorí ibi tí ó dé bá ìdílé wọn.
24 Efuraimu ní ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣeera, òun ló kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati ti ìsàlẹ̀, ati Useni Ṣeera.
25 Orúkọ àwọn ọmọ ati arọmọdọmọ Efuraimu yòókù ni Refa, baba Reṣefu, baba Tela, baba Tahani;
26 baba Ladani, baba Amihudu, baba Eliṣama;
27 baba Nuni, baba Joṣua.
28 Àwọn ilẹ̀ ìní wọn ati àwọn agbègbè tí wọ́n tẹ̀dó sí nìwọ̀nyí: Bẹtẹli, Naarani ní apá ìlà oòrùn, Geseri ní apá ìwọ̀ oòrùn, Ṣekemu ati Aya; pẹlu àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá àyíká wọn.
29 Àwọn ìlú wọnyi wà lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ àwọn ará Manase: Beti Ṣani, Taanaki, Megido, Dori ati gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká.Níbẹ̀ ni àwọn ìran Josẹfu, ọmọ Jakọbu ń gbé.
30 Àwọn ọmọ Aṣeri nìwọ̀nyí: Imina, Iṣifa, Iṣifi ati Beraya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Sera.
31 Beraya bí ọmọkunrin meji: Heberi ati Malikieli, baba Birisaiti.
32 Heberi bí ọmọkunrin mẹta: Jafileti, Ṣomeri ati Hotamu; ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣua.
33 Jafileti bí ọmọ mẹta: Pasaki, Bimihali, ati Aṣifatu.
34 Ṣomeri, arakunrin Jafileti, bí ọmọkunrin mẹta: Roga, Jehuba ati Aramu.
35 Hotamu, arakunrin rẹ̀, bí ọmọkunrin mẹrin: Sofa, Imina, Ṣeleṣi ati Amali.
36 Sofa bí Ṣua, Haneferi, ati Ṣuali; Beri, ati Imira;
37 Beseri, Hodi, ati Ṣama, Ṣiliṣa, Itirani, ati Beera.
38 Jeteri bí: Jefune, Pisipa, ati Ara.
39 Ula bí: Ara, Hanieli ati Risia.
40 Àwọn ni ìran Aṣeri, wọ́n jẹ́ baálé baálé ni ìdílé baba wọn, àṣàyàn akọni jagunjagun, ati olórí láàrin àwọn ìjòyè. Àkọsílẹ̀ iye àwọn tí wọ́n tó ogun jà ninu wọn, ní ìdílé ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtala (26,000).