1 Dafidi kọ́ ọpọlọpọ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó tọ́jú ibìkan fún Àpótí Majẹmu Ọlọrun. Ó sì pa àgọ́ lé e lórí.
2 Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.”
3 Nítorí náà, Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sí Jerusalẹmu, kí wọ́n baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wá sí ibi tí ó pèsè sílẹ̀ fún un.
4 Dafidi kó àwọn ọmọ Aaroni ati àwọn ọmọ Lefi jọ:
5 Iye àwọn ọmọ Lefi tí ó kó jọ láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí: láti inú ìdílé Kohati: ọgọfa (120) ọkunrin, Urieli ni olórí wọn;
6 láti inú ìdílé Merari: igba ó lé ogún (220) ọkunrin, Asaaya ni olórí wọn,
7 láti inú ìdílé Geriṣomu, aadoje (130) ọkunrin, Joẹli ni olórí wọn;
8 láti inú ìdílé Elisafani, igba (200) ọkunrin, Ṣemaaya ni olórí wọn,
9 láti inú ìdílé Heburoni, ọgọrin ọkunrin, Elieli ni olórí wọn,
10 láti inú ìdílé Usieli, ọkunrin mejilelaadọfa (112), Aminadabu ni olórí wọn.
11 Dafidi pe Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa, pẹlu àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi mẹfa, Urieli, Asaaya, ati Joẹli, Ṣemaaya, Elieli, ati Aminadabu,
12 ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí ìdílé yín ninu ẹ̀yà Lefi. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin ati àwọn eniyan yín, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli wá síbi tí mo ti tọ́jú sílẹ̀ fún un.
13 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé e lákọ̀ọ́kọ́, OLUWA Ọlọrun wa jẹ wá níyà, nítorí pé a kò tọ́jú rẹ̀ bí ó ti tọ́.”
14 Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli.
15 Àwọn ọmọ Lefi fi ọ̀pá gbé e lé èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Mose.
16 Dafidi pàṣẹ fún àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n yan àwọn akọrin láàrin ara wọn, tí wọn yóo máa fi ohun èlò orin bíi hapu, dùùrù, ati aro dá orin ayọ̀.
17 Nítorí náà àwọn ọmọ Lefi yan Hemani, ọmọ Joẹli ati Asafu, arakunrin rẹ̀, ọmọ Berekaya, ati àwọn arakunrin wọn láti ìdílé Merari, arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaaya.
18 Wọ́n yan àwọn arakunrin wọn wọnyi kí wọ́n wà ní ipò keji sí wọn: Sakaraya, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Uni, Eliabu, Bẹnaya, Maaseaya, Matitaya, Elifelehu ati Mikineiya, pẹlu àwọn aṣọ́nà: Obedi Edomu ati Jeieli.
19 Wọ́n yan àwọn akọrin, Hemani, Asafu ati Etani láti máa lu aro tí wọ́n fi idẹ ṣe
20 Sakaraya, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Uni, Eliabu, Maaseaya ati Bẹnaya ń lo hapu,
21 ṣugbọn Matitaya, Elifelehu, Mikineiya, Obedi Edomu, Jeieli ati Asasaya ni wọ́n ń tẹ dùùrù.
22 Kenanaya ni a yàn láti máa darí orin àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé ó ní ìmọ̀ orin.
23 Berekaya ati Elikana ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.
24 Àwọn alufaa tí wọ́n yàn láti máa fọn fèrè níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun ni: Ṣebanaya, Joṣafati, Netaneli, Amasa, Sakaraya, Bẹnaya, ati Elieseri. Obedi Edomu ati Jehaya pẹlu ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.
25 Dafidi ati àwọn àgbààgbà Israẹli ati àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun bá lọ sí ilé Obedi Edomu, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ayọ̀.
26 Nítorí pé Ọlọrun ran àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA lọ́wọ́, wọ́n fi mààlúù meje ati àgbò meje rúbọ.
27 Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu, ati àwọn akọrin ati Kenanaya, olórí àwọn akọrin wọ aṣọ funfun tí ń dán, Dafidi sì wọ efodu funfun.
28 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli ṣe gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ìró orin ayọ̀, tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí ohun èlò orin bíi ipè, fèrè, aro, hapu ati dùùrù kọ.
29 Bí wọ́n ti ń gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wọ ìlú Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu yọjú láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi tí ń jó, tí ń fò sókè tayọ̀tayọ̀, ó sì pẹ̀gàn rẹ̀ ninu ara rẹ̀.