1 Àwọn ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Heburoni nìwọ̀nyí, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Aminoni tí Ahinoamu ará Jesireeli bí fún un ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Daniẹli, ọmọ Abigaili ará Kamẹli.
2 Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọbinrin Talimai, ọba ìlú Geṣuri; lẹ́yìn náà Adonija ọmọ Hagiti.
3 Ẹkarun-un ni Ṣefataya, ọmọ Abitali; lẹ́yìn rẹ̀ ni Itireamu ọmọ Egila.
4 Ní Heburoni, níbi tí Dafidi ti jọba fún ọdún meje ati ààbọ̀, ni wọ́n ti bí àwọn mẹfẹẹfa fún un.Lẹ́yìn náà, Dafidi jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹtalelọgbọn.
5 Àwọn ọmọ tí Dafidi bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí:Batiṣeba, ọmọbinrin Amieli, bí ọmọ mẹrin fún un: Ṣimea, Ṣobabu, Natani ati Solomoni.
6 Àwọn ọmọ mẹsan-an mìíràn tí Dafidi tún bí ni: Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti;
7 Noga, Nefegi, ati Jafia,
8 Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti,
9 Dafidi ni ó bí gbogbo wọn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn tún bí fún un. Ó bí ọmọbinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari.
10 Àwọn ọmọ Solomoni ọba nìwọ̀nyí: Rehoboamu, Abija, Asa, ati Jehoṣafati;
11 Joramu, Ahasaya, ati Joaṣi;
12 Amasaya, Asaraya, ati Jotamu;
13 Ahasi, Hesekaya, ati Manase,
14 Amoni ati Josaya.
15 Orúkọ àwọn ọmọ Josaya mẹrẹẹrin, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn ni: Johanani, Jehoiakimu, Sedekaya ati Ṣalumu.
16 Jehoiakimu bí ọmọ meji: Jekonaya ati Sedekaya.
17 Àwọn ọmọ Jehoiakini, ọba tí a mú lẹ́rú lọ sí Babiloni nìwọ̀nyí: Ṣealitieli,
18 Malikiramu, Pedaaya, ati Ṣenasari, Jekamaya, Hoṣama ati Nedabaya.
19 Pedaaya bí ọmọ meji: Serubabeli, ati Ṣimei. Serubabeli bí ọmọ meji: Meṣulamu ati Hananaya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣelomiti.
20 Serubabeli tún bí ọmọ marun-un mìíràn: Haṣuba, Oheli, ati Berekaya; Hasadaya ati Juṣabi Hesedi.
21 Hananaya bí ọmọ meji: Pelataya ati Jeṣaaya, àwọn ọmọ Refaaya, ati ti Arinoni, ati ti Ọbadaya, ati ti Ṣekanaya.
22 Ṣekanaya ní ọmọ kan, tí ń jẹ́ Ṣemaaya. Ṣemaaya bí ọmọ marun-un: Hatuṣi, Igali, Baraya, Nearaya ati Ṣafati.
23 Nearaya bí ọmọ mẹta: Elioenai, Hisikaya ati Asirikamu.
24 Elioenai bí ọmọ meje: Hodafaya, Eliaṣibu, Pelaaya, Akubu, Johanani, Delaaya ati Anani.