Kronika Kinni 9 BM

Àwọn tí Wọ́n Dé láti Oko Ẹrú Babiloni

1 A kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìran wọn; a kọ wọ́n sinu ìwé Àwọn Ọba Israẹli.A kó àwọn ẹ̀yà Juda ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni nítorí pé wọ́n ṣe alaiṣootọ sí Ọlọrun.

2 Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pada dé sórí ilẹ̀ wọn, ní ìlú wọn, ni àwọn ọmọ Israẹli, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹmpili.

3 Àwọn eniyan tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Juda, Bẹnjamini, Efuraimu, ati Manase tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí:

4 Utai ọmọ Amihudu, ọmọ Omiri, ọmọ Imiri, ọmọ Bani, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda.

5 Àwọn ọmọ Ṣilo ni Asaaya, àkọ́bí rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀.

6 Àwọn ọmọ ti Sera ni Jeueli ati àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó dín mẹ́wàá (690).

7 Àwọn tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Salu, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Hodafaya, ọmọ Hasenua,

8 Ibineaya, ọmọ Jerohamu, Ela, ọmọ Usi, ọmọ Mikiri, Meṣulamu, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Reueli, ọmọ Ibinija.

9 Àwọn ìbátan wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti tò wọ́n sinu ìwé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹrindinlọgọta (956). Gbogbo wọn jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn, tí ń gbé Jerusalẹmu.

Àwọn Alufaa Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu

10 Àwọn alufaa tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Jedaaya, Jehoiaribu, Jakini,

11 ati Asaraya ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé Ọlọrun;

12 ati Adaaya, ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Imeri.

13 Àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ilé Ọlọrun láìka àwọn eniyan wọn ati àwọn olórí ìdílé wọn gbogbo jẹ́ ẹgbẹsan ó dín ogoji (1,760).

Àwọn Ọmọ Lefi Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu

14 Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣemaaya ọmọ Haṣihubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, lára àwọn ọmọ Merari;

15 ati Bakibakari, Hereṣi, Galali ati Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sikiri, ọmọ Asafu,

16 ati Ọbadaya ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Galali, ọmọ Jẹdutumu, ati Berekaya ọmọ Asa, ọmọ Elikana, tí ń gbé agbègbè tí àwọn ọmọ Netofa wà.

Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu

17 Àwọn aṣọ́nà Tẹmpili nìwọ̀nyí: Ṣalumu, Akubu, Talimoni, Ahimani, ati àwọn eniyan wọn; (Ṣalumu ni olórí wọn).

18 Wọ́n ń ṣọ́ apá ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn ilé ọba. Àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àgọ́ àwọn ọmọ Lefi tẹ́lẹ̀.

19 Ṣalumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora ati àwọn ará ilé baba rẹ̀. Gbogbo ìdílé Kora ni alabojuto iṣẹ́ ìsìn ninu tẹmpili ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àgọ́, gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti jẹ́ alabojuto Àgọ́ OLUWA ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀.

20 Finehasi, ọmọ Eleasari ni olórí wọn tẹ́lẹ̀ rí, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.

21 Sakaraya, ọmọ Meṣelemaya ni olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

22 Gbogbo àwọn olùṣọ́nà tí wọ́n yàn láti máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé jẹ́ igba ó lé mejila (212). A kọ orúkọ wọn sinu ìwé gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní agbègbè wọn. Dafidi ati Samuẹli aríran, ni wọ́n fi wọ́n sí ipò pataki náà.

23 Nítorí náà, àwọn ati àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ń ṣe alabojuto ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, àwọn ni wọ́n fi ṣe olùṣọ́ Àgọ́ Àjọ.

24 Ọ̀gá aṣọ́nà kọ̀ọ̀kan wà ní ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin: ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìwọ̀ oòrùn, ati àríwá, ati gúsù;

25 àwọn eniyan wọn tí wọn ń gbé àwọn ìletò a máa wá ní ọjọ́ meje meje, láti ìgbà dé ìgbà, láti wà pẹlu àwọn olórí ọ̀gá aṣọ́nà mẹrin náà.

26 Nítorí àwọn olórí mẹrin wọnyi, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, ni wọ́n tún ń ṣe alabojuto àwọn yàrá tẹmpili ati àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé Ọlọrun.

27 Wọ́n ń gbé àyíká ilé Ọlọrun, nítorí iṣẹ́ wọn ni láti máa bojútó o, ati láti máa ṣí ìlẹ̀kùn rẹ̀ ní àràárọ̀.

Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù

28 Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi ni alabojuto àwọn ohun èlò ìjọ́sìn, iṣẹ́ wọn ni láti máa fún àwọn tí wọ́n ń lò wọ́n, ati láti gbà wọ́n pada sí ipò wọn, kí wọ́n sì kà wọ́n kí wọ́n rí i pé wọ́n pé.

29 Iṣẹ́ àwọn mìíràn ninu wọn ni láti máa tọ́jú ohun ọ̀ṣọ́ tẹmpili ati ohun èlò mímọ́, ati ìyẹ̀fun ọkà, waini, òróró, turari, ati òjíá.

30 Àwọn ọmọ alufaa yòókù ni wọ́n ń po turari,

31 Matitaya, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi tí ó jẹ́ àkọ́bí Ṣalumu ará Kora níí máa ń ṣe àkàrà ìrúbọ.

32 Bákan náà, àwọn kan ninu àwọn ọmọ Kohati, ni wọ́n máa ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn ní ọjọọjọ́ ìsinmi.

33 Àwọn ọmọ Lefi kan wà fún orin kíkọ ninu tẹmpili, wọ́n jẹ́ baálé baálé ninu ẹ̀yà Lefi, ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu tẹmpili ni àwọn ń gbé, wọn kì í bá àwọn yòókù ṣiṣẹ́ mìíràn ninu tẹmpili, nítorí pé iṣẹ́ tiwọn ni orin kíkọ tọ̀sán-tòru.

34 Baálé baálé ni àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi ninu ìdílé wọn, olórí ni wọ́n ninu ẹ̀yà Lefi, wọ́n ń gbé Jerusalẹmu.

Àwọn Baba Ńlá ati Àwọn Àtìrandíran Saulu Ọba

35 Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ìlú Gibeoni, iyawo rẹ̀ ń jẹ́ Maaka,

36 Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, Neri, ati Nadabu;

37 Gedori, Ahio, Sakaraya, ati Mikilotu;

38 Mikilotu bí Ṣimea; àwọn náà ń gbé lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn ni òdìkejì ibùgbé àwọn arakunrin wọn ní Jerusalẹmu.

39 Neri ni ó bí Kiṣi, Kiṣi bí Saulu, Saulu ni baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali.

40 Jonatani ni ó bí Meribibaali; Meribibaali sì bí Mika.

41 Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi;

42 Ahasi sì bí Jara. Jara bí ọmọ mẹta: Alemeti, Asimafeti ati Simiri, Simiri bí Mosa,

43 Mosa sì bí Binea. Binea ni baba Refaaya, Refaaya ni ó bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli.

44 Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, ati Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29