Kronika Kinni 29 BM

Àwọn Ẹ̀bùn láti fi Kọ́ Tẹmpili

1 Dafidi ọba sọ fún àpéjọpọ̀ àwọn eniyan pé, “Solomoni ọmọ mi, ẹnìkan ṣoṣo tí Ọlọrun yàn, ó kéré, kò tíì ní ìrírí, iṣẹ́ náà sì tóbi pupọ, nítorí ààfin náà kò ní wà fún eniyan, bíkòṣe fún OLUWA Ọlọrun.

2 Mo ti sa ipá tèmi láti pèsè oríṣìíríṣìí nǹkan sílẹ̀ fún ilé OLUWA: wúrà fún àwọn ohun tí a nílò wúrà fún, fadaka fún àwọn ohun tí a nílò fadaka fún, idẹ fún àwọn ohun tí a nílò idẹ fún, irin fún àwọn ohun tí a nílò irin fún, pákó fún àwọn ohun tí a nílò pákó fún, lẹ́yìn náà, òkúta ìkọ́lé, òkúta olówó iyebíye, àwọn òkúta tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, ati mabu.

3 Lẹ́yìn náà, yàtọ̀ fún gbogbo àwọn nǹkan tí mo ti pèsè fún Tẹmpili Ọlọrun mi, mo ní ilé ìṣúra ti èmi alára, tí ó kún fún wúrà ati fadaka, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ mi sí ilé Ọlọrun mi, mo fi wọ́n sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé náà.

4 Mo ti pèsè ẹgbẹẹdogun (3,000) ìwọ̀n talẹnti wúrà dáradára láti ilẹ̀ Ofiri, ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka tí a ti yọ́, láti fi bo gbogbo ògiri tẹmpili náà,

5 ati àwọn ohun èlò mìíràn tí àwọn oníṣẹ́ ọnà yóo lò: wúrà fún àwọn ohun èlò wúrà, ati fadaka fún àwọn ohun èlò fadaka. Nisinsinyii, ninu yín, ta ló fẹ́ fi tinútinú ṣe ìtọrẹ, tí yóo sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí fún OLUWA?”

6 Nígbà náà ni àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati ti ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn alabojuto ohun ìní ọba, bẹ̀rẹ̀ sí dá ọrẹ àtinúwá jọ.

7 Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé OLUWA nìwọ̀nyí: ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) talẹnti wúrà, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaasan-an (18,000) ìwọ̀n talẹnti idẹ ati ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ìwọ̀n talẹnti irin.

8 Gbogbo àwọn tí wọ́n ní òkúta olówó iyebíye ni wọ́n mú wọn wá tí wọ́n fi wọ́n sí ibi ìṣúra ilé OLUWA, tí ó wà lábẹ́ àbojútó Jehieli ará Geriṣoni.

9 Inú àwọn eniyan náà dùn pé wọ́n fi tinútinú mú ọrẹ wá nítorí pé tọkàntọkàn ati tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n fi mú ọrẹ wá fún OLUWA; inú Dafidi ọba náà sì dùn pupọ pẹlu.

Dafidi Fi Ìyìn fún Ọlọrun

10 Nítorí náà, Dafidi yin OLUWA níwájú gbogbo eniyan, ó ní: “Ìyìn ni fún ọ títí lae, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, Baba ńlá wa,

11 OLUWA, o tóbi pupọ, tìrẹ ni agbára, ògo, ìṣẹ́gun, ati ọlá ńlá; nítorí tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run ati ní ayé. Tìrẹ ni ìjọba, a gbé ọ ga bí orí fún ohun gbogbo.

12 Láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni ọrọ̀ ati ọlá ti ń wá, o sì ń jọba lórí ohun gbogbo. Ìkáwọ́ rẹ ni ipá ati agbára wà, ó wà ní ìkáwọ́ rẹ láti gbéni ga ati láti fún ni lágbára.

13 A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun wa, a sì yin orúkọ rẹ tí ó lógo.

14 “Ṣugbọn, kí ni mo jẹ́, kí sì ni àwọn eniyan mi jẹ́, tí a fi lè mú ọrẹ tí ó pọ̀ tó báyìí wá fún Ọlọrun tọkàntọkàn? Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ninu ohun tí o fún wa ni a sì ti mú wá fún ọ.

15 Àjèjì ati àlejò ni a jẹ́ ní ojú rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá wa. Gbogbo ọjọ́ wa láyé dàbí òjìji, kò lè wà pẹ́ títí.

16 OLUWA, Ọlọrun wa, tìrẹ ni gbogbo ohun tí a mú wá, láti fi kọ́ ilé fún orúkọ mímọ́ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni wọ́n sì ti wá.

17 Ọlọrun mi, mo mọ̀ pé ò máa yẹ ọkàn wò, o sì ní inú dídùn sí òtítọ́; tọkàntọkàn mi ni mo fi mú gbogbo nǹkan wọnyi wá fún ọ, mo sì ti rí i bí àwọn eniyan rẹ ti fi tọkàntọkàn ati inú dídùn mú ọrẹ wọn wá fún ọ.

18 OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa: Abrahamu, Isaaki ati Israẹli, jẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí túbọ̀ máa wà ninu àwọn eniyan rẹ títí lae, kí o sì jẹ́ kí ọkàn wọn máa fà sí ọ̀dọ̀ rẹ.

19 Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Solomoni ọmọ mi, fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa òfin, àṣẹ ati ìlànà rẹ mọ́, kí ó lè ṣe ohun gbogbo, kí ó sì lè kọ́ tẹmpili tí mo ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún.”

20 Dafidi sọ fún gbogbo ìjọ eniyan pé, “Ẹ yin OLUWA Ọlọrun yín.” Gbogbo wọn bá yin OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Wọ́n wólẹ̀, wọ́n sin OLUWA, wọ́n sì tẹríba fún ọba.

21 Ní ọjọ́ keji, wọ́n fi ẹgbẹrun akọ mààlúù rú ẹbọ sísun sí OLUWA, ati ẹgbẹrun àgbò, ati ẹgbẹrun ọ̀dọ́ aguntan, pẹlu ọrẹ ohun mímu ati ọpọlọpọ ẹbọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

22 Wọ́n jẹ, wọ́n sì mu níwájú Ọlọrun ní ọjọ́ náà pẹlu ayọ̀ ńlá.Wọ́n tún fi Solomoni, ọmọ Dafidi, jẹ ọba lẹẹkeji. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba ní orúkọ OLUWA, Sadoku sì ni alufaa.

23 Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọba, dípò Dafidi, baba rẹ̀. Solomoni ní ìlọsíwájú, gbogbo àwọn eniyan Israẹli sì ń gbọ́ tirẹ̀.

24 Gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn alágbára, ati gbogbo àwọn ọmọ Dafidi ọba ni wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa gbọ́ ti Solomoni.

25 OLUWA gbé Solomoni ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fún un ní ọlá ju gbogbo àwọn ọba tí wọ́n ti jẹ ṣáájú rẹ̀ ní Israẹli.

Àkójọpọ̀ Ìjọba Dafidi

26 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi, ọmọ Jese, ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli.

27 Ó jọba fún ogoji ọdún; ó jọba fún ọdún meje ní Heburoni, ó sì jọba fún ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu.

28 Ẹ̀mí rẹ̀ gùn, ó lọ́rọ̀, ó sì lọ́lá, ó sì di arúgbó kàngẹ́kàngẹ́ kí ó tó kú, Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

29 Ìtàn ìgbé ayé ọba Dafidi láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ni a kọ sí inú ìwé ìtàn tí wolii Samuẹli kọ, èyí tí wolii Natani kọ, ati èyí tí wolii Gadi kọ.

30 Àkọsílẹ̀ yìí sọ bí ó ti ṣe ìjọba rẹ̀, bí agbára rẹ̀ ti tó; ati gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí i, ati èyí tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli ati sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29