Kronika Kinni 16 BM

1 Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun kalẹ̀ ninu àgọ́ tí Dafidi ti tọ́jú sílẹ̀ fún un, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú Ọlọrun.

2 Nígbà tí Dafidi rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA,

3 ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, atọkunrin atobinrin, ní burẹdi kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran yíyan kọ̀ọ̀kan ati àkàrà èso resini.

4 Ó sì yan àwọn ọmọ Lefi kan láti máa ṣe ètò ìsìn níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA: láti máa gbadura, láti máa dúpẹ́, ati láti máa yin OLUWA Ọlọrun Israẹli.

5 Asafu ni olórí, àwọn tí ipò wọn tún tẹ̀lé tirẹ̀ ni: Sakaraya, Jeieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Matitaya, Eliabu, Bẹnaya, Obedi Edomu ati Jeieli àwọn tí wọ́n ń ta hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù. Asafu ni ó ń lu aro.

6 Bẹnaya ati Jahasieli, tí wọ́n jẹ́ alufaa, ni wọ́n ń fọn fèrè nígbà gbogbo níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun.

7 Ní ọjọ́ náà, àṣẹ àkọ́kọ́ tí Dafidi pa ni pé kí Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ máa kọ orin ìyìn sí OLUWA.

Orin Ìyìn

8 Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA, ẹ képe orúkọ rẹ̀,ẹ kéde ohun tí ó ti ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè.

9 Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn sí i,ẹ sọ nípa àwọn ohun ìyanu tí ó ṣe!

10 Ẹ máa fi orúkọ rẹ̀ ṣògo,kí ọkàn àwọn tí wọn ń sin OLUWA kún fún ayọ̀.

11 OLUWA ni kí ẹ máa tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́,Ẹ máa sìn ín nígbà gbogbo.

12 Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,gbogbo nǹkan ìyanu tí ó ṣe, ati gbogbo ìdájọ́ rẹ̀,

13 ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

14 Òun ni OLUWA Ọlọrun wa,ìdájọ́ rẹ̀ ká gbogbo ayé.

15 Kò ní í gbàgbé majẹmu rẹ̀ títí lae,àní àwọn ohun tí ó ti pa láṣẹ láti ṣe fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,

16 majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,ìlérí tí ó ti ṣe fún Isaaki,

17 tí ó sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu Jakọbu,gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ohun tí yóo wà títí lae,

18 ó ní, “Ẹ̀yin ni n óo fún ní ilẹ̀ Kenaani,bí ohun ìní yín, tí ẹ óo jogún.”

19 Nígbà tí wọn kò tíì pọ̀ pupọ,tí wọn kò sì jẹ́ nǹkan,tí wọ́n jẹ́ àjèjì níbẹ̀,

20 tí wọn ń lọ káàkiri láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji,láti ìjọba kan sí òmíràn,

21 kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.

22 Ó ní, “Ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,ẹ má sì pa àwọn wolii mi lára!”

23 Ẹ kọrin sí OLUWA, gbogbo ayé!Ẹ máa kéde ìgbàlà rẹ̀ lojoojumọ.

24 Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan!

25 OLUWA tóbi, ìyìn tọ́ sí i lọpọlọpọó sì yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún un ju gbogbo àwọn oriṣa lọ.

26 Nítorí pé ère lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù sọ di ọlọrun,ṣugbọn OLUWA ló dá ọ̀run.

27 Ògo ati agbára yí i ká,ayọ̀ ati ìyìn sì kún Tẹmpili rẹ̀.

28 Ẹ fi ògo fún OLUWA, gbogbo ayé,ẹ gbé ògo ati agbára wọ̀ ọ́!

29 Ẹ fi ògo tí ó yẹ orúkọ OLUWA fún un,ẹ mú ọrẹ wá sí iwájú rẹ̀!Ẹ sin OLUWA pẹlu ẹwà mímọ́,

30 ẹ wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé,ó fi ìdí ayé múlẹ̀ gbọningbọnin kò sì lè yẹ̀ lae.

31 Kí inú ọ̀run kí ó dùn,kí ayé kí ó yọ̀,kí wọ́n sọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé “OLUWA jọba!”

32 Kí òkun ati ohun gbogbo tó wà ninu rẹ̀ hó yèè,kí pápá oko búsáyọ̀, ati gbogbo ẹ̀dá tó wà ninu rẹ̀.

33 Àwọn igi igbó yóo kọrin ayọ̀níwájú OLUWA, nítorí ó wá láti ṣe ìdájọ́ ayé.

34 Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA nítorí pé ó ṣeun,ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ sì wà títí lae!

35 Ẹ kígbe pé, “Gbà wá, Ọlọrun, olùgbàlà wa,kó wa jọ, sì gbà wá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,kí á lè máa dúpẹ́, kí á máa yin orúkọ mímọ́ rẹ,kí á sì máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.

36 Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli,lae ati laelae!”Gbogbo àwọn eniyan sì dáhùn pe, “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA.

Ìjọ́sìn ní Gibeoni ati ní Jerusalẹmu

37 Dafidi fi Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí iwájú Àpótí Majẹmu OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ lojoojumọ,

38 pẹlu Obedi Edomu ati àwọn arakunrin rẹ̀ mejidinlaadọrin; ó sì fi Obedi Edomu, ọmọ Jedutuni ati Hosa ṣe aṣọ́nà.

39 Ó fi Sadoku, alufaa ati àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ibi Àgọ́ OLUWA ní ibi pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Gibeoni,

40 láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ ẹbọ sísun, ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́, bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli.

41 Hemani wà pẹlu wọn, ati Jedutuni ati àwọn mìíràn tí a yàn, tí a sì dárúkọ, láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

42 Hemani ati Jedutuni ní fèrè, aro, ati àwọn ohun èlò ìkọrin mìíràn tí wọ́n fi ń kọrin ìyìn. Àwọn ọmọ Jedutuni ni wọ́n yàn láti máa ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà.

43 Lẹ́yìn náà olukuluku pada sí ilé rẹ̀, Dafidi náà pada sí ilé rẹ̀ láti lọ súre fún àwọn ará ilé rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29