1 Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Geṣomu, Kohati ati Merari.
2 Kohati bí ọmọkunrin mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli.
3 Amramu bí ọmọ mẹta: Aaroni, Mose, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu.Aaroni bí ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.
4 Ìran Eleasari ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Eleasari ni baba Finehasi, Finehasi ni ó bí Abiṣua;
5 Abiṣua bí Buki, Buki sì bí Usi.
6 Usi ni baba Serahaya, Serahaya ló bí Meraiotu,
7 Meraiotu bí Amaraya, Amaraya sì bí Ahitubu.
8 Ahitubu ni baba Sadoku, Sadoku bí Ahimaasi,
9 Ahimaasi bí Asaraya, Asaraya sì bí Johanani.
10 Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).
11 Asaraya ni baba Amaraya, Amaraya ni ó bí Ahitubu;
12 Ahitubu bí Sadoku, Sadoku sì bí Ṣalumu.
13 Ṣalumu ni baba Hilikaya; Hilikaya bí Asaraya,
14 Asaraya bí Seraaya; Seraaya sì bí Jehosadaki.
15 Jehosadaki lọ sí ìgbèkùn nígbà tí Ọlọrun jẹ́ kí Nebukadinesari wá kó Juda ati Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.
16 Àwọn ọmọ Lefi ni: Geriṣoni, Kohati ati Merari.
17 Àwọn ọmọ Geriṣoni ni: Libini ati Ṣimei.
18 Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli.
19 Àwọn ọmọ Merari ni: Mahili ati Muṣi. Àwọn ni baba ńlá àwọn ọmọ Lefi.
20 Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Geriṣoni nìwọ̀nyí: Libini ni baba Jahati, Jahati bí Sima,
21 Sima bí Joa, Joa bí Ido, Ido bí Sera, Sera sì bí, Jeaterai.
22 Àwọn tí ó ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kohati nìwọ̀nyí: Aminadabu ni baba Kora, Kora ló bí Asiri;
23 Asiri bí Elikana, Elikana bí Ebiasafu, Ebiasafu sì bí Asiri.
24 Asiri ni baba Tahati, Tahati ló bí Urieli, Urieli bí Usaya, Usaya sì bí Saulu.
25 Ọmọ meji ni Elikana bí: Amasai ati Ahimotu.
26 Àwọn ọmọ Ahimotu nìwọ̀nyí: Elikana ni baba Sofai, Sofai ni ó bí Nahati;
27 Nahati bí Eliabu, Eliabu bí Jerohamu, Jerohamu sì bí Elikana.
28 Samuẹli bí ọmọkunrin meji: Joẹli ni àkọ́bí, Abija sì ni ikeji.
29 Àwọn ọmọ Merari nìwọ̀nyí: Mahili ni baba Libini, Libini bí Ṣimei,
30 Ṣimei bí Usali, Usali bí Ṣimea, Ṣimea bí Hagaya, Hagaya sì bí Asaya.
31 Dafidi fi àwọn wọnyi ṣe alákòóso ẹgbẹ́ akọrin ninu ilé OLUWA lẹ́yìn tí wọn ti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sibẹ;
32 àwọn ni wọ́n ń kọ orin ninu Àgọ́ Àjọ títí tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA parí ní Jerusalẹmu; àṣegbà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn.
33 Àwọn tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà, pẹlu àwọn ọmọ wọn nìwọ̀nyí:Ninu ìdílé Kohati: Hemani, akọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,
34 ọmọ Elikana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toa,
35 ọmọ Sufu, ọmọ Elikana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,
36 ọmọ Elikana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asaraya, ọmọ Sefanaya,
37 ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora,
38 ọmọ Iṣari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli.
39 Asafu, arakunrin rẹ̀, ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá ọ̀tun rẹ̀. Asafu yìí jẹ́ ọmọ Berekaya, ọmọ Ṣimea;
40 Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseaya, ọmọ Malikija,
41 ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaya;
42 ọmọ Etani, ọmọ Sima, ọmọ Ṣimei,
43 ọmọ Jahati, ọmọ Geriṣomu, ọmọ Lefi.
44 Etani arakunrin wọn láti inú ìdílé Merari ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá òsì rẹ̀. Ìran Etani títí lọ kan Lefi nìyí: ọmọ Kiṣi ni Etani, ọmọ Abidi, ọmọ Maluki;
45 ọmọ Haṣabaya, ọmọ Amasaya, ọmọ Hilikaya;
46 ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri;
47 ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.
48 Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi, arakunrin wọn yòókù láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó kù ninu ilé Ọlọrun.
49 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun ati lórí pẹpẹ turari; àwọn ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn ninu ibi mímọ́ jùlọ, tí wọ́n sì máa ń ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose, iranṣẹ Ọlọrun là sílẹ̀.
50 Àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí: Eleasari baba Finehasi, baba Abiṣua;
51 baba Buki, baba Usi, baba Serahaya;
52 baba Meraiotu, baba Amaraya, baba Ahitubu;
53 baba Sadoku, baba Ahimaasi.
54 Ilẹ̀ tí a pín fún ìran Aaroni nìyí, pẹlu ààlà wọn: ìdílé Kohati ni a kọ́kọ́ pín ilẹ̀ fún ninu àwọn ọmọ Lefi.
55 Wọ́n fún wọn ní ìlú Heburoni ní ilẹ̀ Juda, ati gbogbo ilẹ̀ pápá oko tí ó yí i ká,
56 ṣugbọn Kalebu ọmọ Jefune ni wọ́n fún ní ìgbèríko ati ìletò tí ó yí ìlú Heburoni ká.
57 Àwọn ọmọ Aaroni ni a pín àwọn ìlú ààbò wọnyi fún: Heburoni, Libina, Jatiri ati Eṣitemoa, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.
58 Bẹ́ẹ̀ náà ni Hileni, ati Debiri,
59 ati Aṣani ati Beti Ṣemeṣi pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká.
60 Àwọn ìlú tí wọ́n pín fún wọn, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini nìwọ̀nyí: Geba, Alemeti, ati Anatoti, pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká. Gbogbo àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní gbogbo ìdílé wọn jẹ́ mẹtala.
61 Gègé ni wọ́n ṣẹ́ lórí ìlú mẹ́wàá ara ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, tí wọn sì pín wọn fún àwọn ìdílé Kohati tí ó kù.
62 Ìlú mẹtala ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Geriṣomu ní ìdílé ìdílé lára àwọn ìlú ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Baṣani.
63 Ìlú mejila ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Merari ní ìdílé ìdílé, lára àwọn ìlú ẹ̀yà Reubẹni, Gadi ati ti Sebuluni.
64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo àwọn ìlú ńláńlá pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.
65 Wọ́n tún ṣẹ́ gègé láti fún wọn ní àwọn ìlú ńláńlá tí a dárúkọ wọnyi lára ìlú àwọn ẹ̀yà Juda, Simeoni ati ti Bẹnjamini.
66 Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti pín àwọn ìlú ńláńlá fún àwọn ìdílé kan ninu àwọn ọmọ Kohati.
67 Àwọn ìlú ààbò tí wọ́n fún wọn, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká, ní agbègbè olókè Efuraimu nìwọ̀nyí; Ṣekemu, ati Geseri;
68 Jokimeamu ati Beti Horoni;
69 Aijaloni ati Gati Rimoni.
70 Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Kohati tí ó kù ní Aneri ati Bileamu, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.
71 Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká: Golani ní ilẹ̀ Baṣani, ati Aṣitarotu.
72 Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari; wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ati Daberati;
73 Ramoti ati Anemu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
74 Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní Maṣali ati Abidoni;
75 Hukoku ati Rehobu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
76 Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Galili, Hamoni, ati Kiriataimu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
77 Wọ́n pín àwọn ìlú wọnyi fún àwọn ìdílé tí ó kù ninu àwọn ọmọ Merari.Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní Rimono ati Tabori, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
78 Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní ìkọjá Jọdani níwájú Jẹriko, wọ́n fún wọn ní Beseri tí ó wà ní ara òkè, ati Jahasa,
79 Kedemotu ati Mefaati pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
80 Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní Ramoti ní ilẹ̀ Gileadi ati Mahanaimu,
81 Heṣiboni ati Jaseri, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.